3 Ó dájú pé àṣẹ tí Jèhófà pa ló mú kí èyí ṣẹlẹ̀ sí Júdà, kí ó lè mú wọn kúrò níwájú rẹ̀+ nítorí gbogbo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí Mánásè dá+ 4 àti nítorí ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí ó ta sílẹ̀,+ torí ó ti fi ẹ̀jẹ̀ àwọn aláìṣẹ̀ kún Jerúsálẹ́mù, Jèhófà kò sì fẹ́ dárí jì wọ́n.+