3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí.
3 Nítorí, “wò ó! ọjọ́ ń bọ̀,” ni Jèhófà wí, “tí màá kó àwọn èèyàn mi, Ísírẹ́lì àti Júdà, tó wà lóko ẹrú jọ,”+ ni Jèhófà wí, “màá mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá wọn, yóò sì pa dà jẹ́ tiwọn.”’”+