15 Nítorí náà, ọjọ́ méjìléláàádọ́ta (52) la fi mọ ògiri náà, ó sì parí ní ọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n oṣù Élúlì.
16 Nígbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá wa gbọ́, tí gbogbo orílẹ̀-èdè tó yí wa ká sì rí i, ìtìjú ńlá bá wọn,+ wọ́n sì rí i pé Ọlọ́run wa ló ràn wá lọ́wọ́ tí a fi lè parí iṣẹ́ náà.