9 Idà àti ìyàn pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn ni yóò pa àwọn tó bá dúró nínú ìlú yìí. Àmọ́ ẹni tó bá jáde, tó sì fi ara rẹ̀ lé ọwọ́ àwọn ará Kálídíà tí wọ́n dó tì yín, á máa wà láàyè, á sì jèrè ẹ̀mí rẹ̀.”’*+
12 Mo tún bá Ọba Sedekáyà+ ti Júdà sọ̀rọ̀ lọ́nà kan náà pé: “Ẹ mú ọrùn yín wá sábẹ́ àjàgà ọba Bábílónì, kí ẹ sì sin òun àti àwọn èèyàn rẹ̀, kí ẹ lè máa wà láàyè.+