13 Jóhánánì ọmọ Káréà àti gbogbo olórí àwọn ọmọ ogun tó wà ní pápá wá sọ́dọ̀ Gẹdaláyà ní Mísípà. 14 Wọ́n sọ fún un pé: “Ṣé o kò mọ̀ pé Báálísì, ọba àwọn ọmọ Ámónì,+ ti rán Íṣímáẹ́lì ọmọ Netanáyà láti wá pa ọ́?”+ Ṣùgbọ́n Gẹdaláyà ọmọ Áhíkámù kò gbà wọ́n gbọ́.