ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 5:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  9 Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ti búra ní etí mi,

      Pé ọ̀pọ̀ ilé, bí wọ́n tiẹ̀ tóbi, tí wọ́n sì rẹwà,

      Wọ́n máa di ohun àríbẹ̀rù,

      Láìsí olùgbé kankan.+

  • Àìsáyà 6:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Ni mo bá sọ pé: “Títí dìgbà wo, Jèhófà?” Ó dáhùn pé:

      “Títí àwọn ìlú náà fi máa fọ́ túútúú, tí kò sì ní sẹ́ni tó ń gbé ibẹ̀,

      Tí kò ní sẹ́nì kankan nínú àwọn ilé,

      Títí ilẹ̀ náà fi máa pa run, tó sì máa di ahoro;+

  • Jeremáyà 2:15
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 15 Àwọn ọmọ kìnnìún* ké ramúramù mọ́ ọn;+

      Wọ́n gbé ohùn wọn sókè.

      Wọ́n sì sọ ilẹ̀ rẹ̀ di ohun tó ń bani lẹ́rù.

      Wọ́n ti sọ iná sí àwọn ìlú rẹ̀, tí kò fi sí ẹnì kankan tó ń gbé ibẹ̀.

  • Jeremáyà 9:11
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 11 Màá sọ Jerúsálẹ́mù di òkìtì òkúta,+ ibùgbé àwọn ajáko,*+

      Màá sì sọ àwọn ìlú Júdà di ahoro, tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé ibẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́