19 Ẹni ọdún méjìlélógún (22) ni Ámọ́nì+ nígbà tó jọba, ọdún méjì ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Méṣúlémétì ọmọ Hárúsì láti Jótíbà. 20 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà bí Mánásè bàbá rẹ̀ ti ṣe.+
8 Ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) ni Jèhóákínì+ nígbà tó jọba, oṣù mẹ́ta ló sì fi ṣàkóso ní Jerúsálẹ́mù.+ Orúkọ ìyá rẹ̀ ni Néhúṣítà ọmọ Élínátánì láti Jerúsálẹ́mù. 9 Ó ń ṣe ohun tó burú ní ojú Jèhófà, gbogbo ohun tí bàbá rẹ̀ ṣe ni òun náà ṣe.