- 
	                        
            
            Ọbadáyà 2-4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        2 “Wò ó! Mo ti sọ ọ́ di ẹni tí kò já mọ́ nǹkan kan láàárín àwọn orílẹ̀-èdè; O ti tẹ́ pátápátá.+ 3 Ìgbéraga* ọkàn rẹ ti tàn ọ́ jẹ,+ Ìwọ tó ń gbé ihò inú àpáta, Ìwọ tó ń gbé ibi gíga, tí o sì ń sọ nínú ọkàn rẹ pé, ‘Ta ló lè rẹ̀ mí wálẹ̀?’ 4 Bí o bá tiẹ̀ kọ́lé sí ibi gíga* bí ẹyẹ idì, Tàbí tí o kọ́ ìtẹ́ rẹ sáàárín àwọn ìràwọ̀, Màá rẹ̀ ọ́ wálẹ̀ láti ibẹ̀,” ni Jèhófà wí. 
 
-