ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Àìsáyà 48:20
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 20 Ẹ jáde kúrò ní Bábílónì!+

      Ẹ sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà!

      Ẹ fi igbe ayọ̀ polongo rẹ̀! Ẹ kéde rẹ̀!+

      Ẹ jẹ́ kó di mímọ̀ dé àwọn ìkángun ayé.+

      Ẹ sọ pé: “Jèhófà ti tún Jékọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ rà.+

  • Jeremáyà 51:6
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  6 Ẹ sá kúrò nínú Bábílónì,

      Kí ẹ sì sá nítorí ẹ̀mí* yín.+

      Ẹ má ṣègbé nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.

      Nítorí àkókò ẹ̀san Jèhófà ti tó.

      Ó máa san ohun tó ṣe pa dà fún un.+

  • Jeremáyà 51:45
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 45 Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi!+

      Ẹ sá nítorí ẹ̀mí* yín+ kí ẹ lè bọ́ lọ́wọ́ ìbínú Jèhófà tó ń jó bí iná.+

  • Sekaráyà 2:7
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 7 “Wá, Síónì! Sá àsálà, ìwọ tí ń gbé pẹ̀lú ọmọbìnrin Bábílónì.+

  • 2 Kọ́ríńtì 6:17
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 17 “‘Nítorí náà, ẹ jáde kúrò láàárín wọn, kí ẹ sì ya ara yín sọ́tọ̀,’ ni Jèhófà* wí, ‘ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ mọ́’”;+ “‘màá sì gbà yín wọlé.’”+

  • Ìfihàn 18:2
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 2 Ó sì fi ohùn tó le ké jáde pé: “Ó ti ṣubú! Bábílónì Ńlá ti ṣubú,+ ó sì ti di ibi tí àwọn ẹ̀mí èṣù ń gbé àti ibi tí gbogbo ẹ̀mí àìmọ́* àti gbogbo ẹyẹ àìmọ́ tí a kórìíra ń lúgọ sí!+

  • Ìfihàn 18:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 4 Mo gbọ́ ohùn míì láti ọ̀run, ó sọ pé: “Ẹ jáde kúrò nínú rẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi,+ tí ẹ kò bá fẹ́ pín nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ẹ kò bá sì fẹ́ gbà lára àwọn ìyọnu rẹ̀.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́