35 ‘Kí ìwà ipá tí wọ́n hù sí mi àti sí ara mi wá sórí Bábílónì!’ ni ẹni tó ń gbé Síónì wí.+
‘Kí ẹ̀jẹ̀ mi sì wá sórí àwọn tó ń gbé Kálídíà!’ ni Jerúsálẹ́mù wí.”
36 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
“Wò ó, màá gba ẹjọ́ rẹ rò,+
Màá gbẹ̀san fún ọ.+
Màá mú kí omi òkun rẹ̀ gbẹ, màá sì mú kí àwọn kànga rẹ̀ gbẹ.+