-
Hábákúkù 2:9Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
9 Ẹni tó ń kó èrè tí kò tọ́ jọ fún ilé rẹ̀ gbé!
Kó lè kọ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí ibi gíga,
Kó má bàa kó sínú àjálù.
-
-
Ìfihàn 18:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 “Bákan náà, àwọn oníṣòwò ayé ń sunkún, wọ́n sì ń ṣọ̀fọ̀ lórí rẹ̀, torí kò sí ẹni tó máa ra ọjà wọn tó kún fọ́fọ́ mọ́, 12 ọjà tó kún fún wúrà, fàdákà, àwọn òkúta iyebíye, péálì, aṣọ ọ̀gbọ̀ tó dáa,* aṣọ aláwọ̀ pọ́pù, sílíìkì àti aṣọ aláwọ̀ rírẹ̀dòdò; àti gbogbo ohun tí wọ́n fi igi tó ń ta sánsán ṣe; àti oríṣiríṣi àwọn ohun tí wọ́n fi eyín erin ṣe àtàwọn èyí tí wọ́n fi oríṣiríṣi igi iyebíye ṣe àti bàbà, irin pẹ̀lú òkúta mábù;
-