-
2 Àwọn Ọba 25:27-30Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
27 Ní ọdún kẹtàdínlógójì tí Jèhóákínì+ ọba Júdà ti wà ní ìgbèkùn, ní oṣù kejìlá, ní ọjọ́ kẹtàdínlọ́gbọ̀n oṣù náà, Efili-méródákì ọba Bábílónì, ní ọdún tó jọba, dá Jèhóákínì ọba Júdà sílẹ̀* lẹ́wọ̀n.+ 28 Ó bá a sọ̀rọ̀ pẹ̀lẹ́, ó sì gbé ìtẹ́ rẹ̀ ga ju ìtẹ́ àwọn ọba yòókù tó wà pẹ̀lú rẹ̀ ní Bábílónì. 29 Torí náà, Jèhóákínì bọ́ ẹ̀wù ẹ̀wọ̀n rẹ̀, iwájú ọba ló sì ti ń jẹun déédéé ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀. 30 Ó ń rí oúnjẹ gbà déédéé látọ̀dọ̀ ọba, lójoojúmọ́ ayé rẹ̀.
-