9 “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí, ‘Ẹ dá ẹjọ́ òdodo,+ kí ìfẹ́ tí ẹ ní sí ara yín má yẹ̀,+ kí ẹ sì máa ṣàánú ara yín. 10 Ẹ má lu opó tàbí ọmọ aláìníbaba ní jìbìtì,+ ẹ má lu àjèjì tàbí aláìní ní jìbìtì,+ ẹ má sì gbèrò ibi sí ara yín nínú ọkàn yín.’+