7 “Rántí, má sì gbàgbé bí o ṣe múnú bí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní aginjù.+ Láti ọjọ́ tí ẹ ti kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì títí ẹ fi dé ibí yìí lẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà.+
8 Bí wọ́n ti ń ṣe láti ọjọ́ tí mo ti mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì ni wọ́n ń ṣe títí di òní yìí; wọ́n á fi mí sílẹ̀,+ wọ́n á sì lọ máa sin àwọn ọlọ́run míì,+ ohun kan náà ni wọ́n ń ṣe sí ọ báyìí.