17 ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Wò ó, màá rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn*+ sí wọn, màá sì ṣe wọ́n bí ọ̀pọ̀tọ́ jíjẹrà* tó ti bà jẹ́ débi pé kò ṣeé jẹ.”’+
2 O máa fi iná sun ìdá mẹ́ta irun náà nínú ìlú náà nígbà tí ọjọ́ tí wọ́n dó tì í bá pé.+ O máa kó ìdá mẹ́ta míì, o sì máa fi idà gé e káàkiri ìlú náà,+ kí o wá fọ́n ìdá mẹ́ta yòókù sínú afẹ́fẹ́, èmi yóò sì mú idà kí n lè lé wọn bá.+