17 Àmọ́ wọn ò fetí sí àwọn onídàájọ́ náà pàápàá, wọ́n tún máa ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run míì,* wọ́n sì máa ń forí balẹ̀ fún wọn. Kò pẹ́ tí wọ́n fi yà kúrò ní ọ̀nà tí àwọn baba ńlá wọn rìn, àwọn tó tẹ̀ lé àṣẹ Jèhófà.+ Wọn ò ṣe bíi tiwọn.
8 Bí wọ́n ti ń ṣe láti ọjọ́ tí mo ti mú wọn jáde kúrò ní Íjíbítì ni wọ́n ń ṣe títí di òní yìí; wọ́n á fi mí sílẹ̀,+ wọ́n á sì lọ máa sin àwọn ọlọ́run míì,+ ohun kan náà ni wọ́n ń ṣe sí ọ báyìí.
17 Nítorí pé wọ́n ti fi mí sílẹ̀, wọ́n sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí àwọn ọlọ́run míì+ láti fi gbogbo iṣẹ́ ọwọ́ wọn mú mi bínú,+ ìbínú mi máa bẹ̀rẹ̀ sí í jó bí iná lórí ibí yìí, kò sì ní ṣeé pa.’”+