- 
	                        
            
            Ẹ́sírà 9:6Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        6 Mo sọ pé: “Ìwọ Ọlọ́run mi, ojú ń tì mí, ara sì ń tì mí láti gbé ojú mi sókè sí ọ, ìwọ Ọlọ́run mi, nítorí pé ẹ̀ṣẹ̀ wa ti pọ̀ gan-an lórí wa, ẹ̀bi wa sì ti ga dé ọ̀run.+ 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Nehemáyà 9:33Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        33 O ò lẹ́bi kankan nínú gbogbo ohun tó dé bá wa, nítorí òótọ́ lo fi bá wa lò; àwa la hùwà burúkú.+ 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Dáníẹ́lì 9:5Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        5 a ti ṣẹ̀, a sì ti ṣe ohun tí kò dáa, a ti hùwà burúkú, a sì ti ṣọ̀tẹ̀;+ a ti kọ àwọn àṣẹ rẹ àti àwọn ìdájọ́ rẹ sílẹ̀. 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Dáníẹ́lì 9:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        8 “Jèhófà, àwa ni ìtìjú bá, àwọn ọba wa, àwọn ìjòyè wa àti àwọn baba ńlá wa, torí pé a ti ṣẹ̀ ọ́. 
 
-