- 
	                        
            
            Ìsíkíẹ́lì 3:1-3Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        3 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ ohun tó wà níwájú rẹ.* Jẹ àkájọ ìwé yìí, kí o sì lọ bá ilé Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀.”+ 2 Torí náà, mo la ẹnu mi, ó sì fún mi ní àkájọ ìwé náà pé kí n jẹ ẹ́. 3 Ó wá sọ fún mi pé: “Ọmọ èèyàn, jẹ àkájọ ìwé tí mo fún ọ yìí, kí o sì jẹ ẹ́ yó.” Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ẹ́, ó sì dùn bí oyin lẹ́nu mi.+ 
 
- 
                                        
- 
	                        
            
            Ìfihàn 10:9, 10Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
- 
                            - 
                                        9 Mo lọ bá áńgẹ́lì náà, mo sì sọ fún un pé kó fún mi ní àkájọ ìwé kékeré náà. Ó sọ fún mi pé: “Gbà, kí o jẹ ẹ́ tán,+ ó máa mú kí ikùn rẹ korò, àmọ́ ó máa dùn bí oyin ní ẹnu rẹ.” 10 Mo gba àkájọ ìwé kékeré náà ní ọwọ́ áńgẹ́lì náà, mo sì jẹ ẹ́,+ ó dùn bí oyin ní ẹnu mi,+ àmọ́ nígbà tí mo jẹ ẹ́ tán, ó mú kí ikùn mi korò. 
 
-