18 Àwọn ọmọ ń kó igi jọ, àwọn bàbá ń dá iná, àwọn ìyàwó sì ń po ìyẹ̀fun láti fi ṣe àkàrà ìrúbọ sí Ọbabìnrin Ọ̀run,*+ wọ́n sì ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì láti mú mi bínú.+
29 Àwọn ará Kálídíà tó ń bá ìlú yìí jà máa wọlé wá, wọ́n á sọ iná sí i, wọ́n á sì sun ún kanlẹ̀+ pẹ̀lú àwọn ilé tí àwọn èèyàn náà ti ń rú ẹbọ lórí òrùlé wọn sí Báálì, tí wọ́n sì ti ń da ọrẹ ohun mímu sí àwọn ọlọ́run míì láti mú mi bínú.’+