21 Jèhófà máa mú kí àrùn ṣe ọ́ títí ó fi máa pa ọ́ run ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+22 Jèhófà máa fi ikọ́ ẹ̀gbẹ kọ lù ọ́, pẹ̀lú akọ ibà,+ ara wíwú, ara gbígbóná, idà,+ ooru tó ń jó nǹkan gbẹ àti èbíbu;+ wọ́n á sì bá ọ títí o fi máa ṣègbé.
15 Idà wà níta,+ àjàkálẹ̀ àrùn àti ìyàn sì wà nínú. Idà ni yóò pa ẹnikẹ́ni tó bá wà ní pápá, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa run àwọn tó bá wà nínú ìlú.+