-
Ìsíkíẹ́lì 26:7, 8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
7 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Èmi yóò mú kí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì gbéjà ko Tírè láti àríwá;+ ọba àwọn ọba ni,+ pẹ̀lú àwọn ẹṣin,+ kẹ̀kẹ́ ogun,+ àwọn tó ń gẹṣin àti ọ̀pọ̀ ọmọ ogun.* 8 Yóò fi idà pa àwọn agbègbè tó wà ní ìgbèríko rẹ run, yóò mọ odi láti gbéjà kò ọ́, yóò mọ òkìtì láti dó tì ọ́, yóò sì fi apata ńlá bá ọ jà.
-