Jeremáyà 2:20 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 20 ‘Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti ṣẹ́ àjàgà rẹ sí wẹ́wẹ́+Mo sì já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ. Ṣùgbọ́n, o sọ pé: “Mi ò ní sìn ọ́,” Torí pé orí gbogbo òkè àti abẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀+ Ni o nà gbalaja sí, tí ò ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+ Ìsíkíẹ́lì 16:28, 29 Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun 28 “‘Torí kò tẹ́ ọ lọ́rùn, o tún bá àwọn ọmọ Ásíríà ṣèṣekúṣe.+ Síbẹ̀ ìṣekúṣe tí o bá wọn ṣe yẹn kò tẹ́ ọ lọ́rùn. 29 O tún lọ ṣèṣekúṣe ní ilẹ̀ àwọn oníṣòwò* àti lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà,+ síbẹ̀, kò tẹ́ ọ lọ́rùn.
20 ‘Tipẹ́tipẹ́ ni mo ti ṣẹ́ àjàgà rẹ sí wẹ́wẹ́+Mo sì já ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ rẹ. Ṣùgbọ́n, o sọ pé: “Mi ò ní sìn ọ́,” Torí pé orí gbogbo òkè àti abẹ́ gbogbo igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀+ Ni o nà gbalaja sí, tí ò ń ṣe iṣẹ́ aṣẹ́wó.+
28 “‘Torí kò tẹ́ ọ lọ́rùn, o tún bá àwọn ọmọ Ásíríà ṣèṣekúṣe.+ Síbẹ̀ ìṣekúṣe tí o bá wọn ṣe yẹn kò tẹ́ ọ lọ́rùn. 29 O tún lọ ṣèṣekúṣe ní ilẹ̀ àwọn oníṣòwò* àti lọ́dọ̀ àwọn ará Kálídíà,+ síbẹ̀, kò tẹ́ ọ lọ́rùn.