-
2 Àwọn Ọba 24:15, 16Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Bó ṣe mú Jèhóákínì+ lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì+ nìyẹn; ó tún mú ìyá ọba, àwọn ìyàwó ọba, àwọn òṣìṣẹ́ ààfin àti àwọn aṣáájú ilẹ̀ náà, ó sì kó wọn ní ìgbèkùn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì. 16 Ọba Bábílónì tún kó gbogbo àwọn jagunjagun lọ sí ìgbèkùn ní Bábílónì, ẹgbẹ̀rún méje (7,000) ni wọ́n àti ẹgbẹ̀rún kan (1,000) àwọn oníṣẹ́ ọnà àti àwọn oníṣẹ́ irin,* alágbára ni gbogbo wọn, wọ́n sì ti kọ́ iṣẹ́ ogun.
-
-
Jeremáyà 24:1Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Lẹ́yìn náà, Jèhófà fi apẹ̀rẹ̀ méjì tí ọ̀pọ̀tọ́ wà nínú wọn níwájú tẹ́ńpìlì Jèhófà hàn mí. Èyí wáyé lẹ́yìn tí Nebukadinésárì* ọba Bábílónì mú Jekonáyà*+ ọmọ Jèhóákímù,+ ọba Júdà lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn ìjòyè Júdà àti àwọn oníṣẹ́ ọnà pẹ̀lú àwọn oníṣẹ́ irin.* Ó kó wọn láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Bábílónì.+
-