-
Hébérù 8:8-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Torí ó ń rí àléébù lára àwọn èèyàn nígbà tó sọ pé: “‘Wò ó! Ọjọ́ ń bọ̀,’ ni Jèhófà* wí, ‘tí màá bá ilé Ísírẹ́lì àti ilé Júdà dá májẹ̀mú tuntun. 9 Kò ní dà bíi májẹ̀mú tí mo bá àwọn baba ńlá wọn dá ní ọjọ́ tí mo dì wọ́n lọ́wọ́ mú láti mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ torí pé wọn ò pa májẹ̀mú mi mọ́, ìdí nìyẹn tí mi ò fi bójú tó wọn mọ́,’ ni Jèhófà* wí.
10 “‘Nítorí májẹ̀mú tí màá bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,’ ni Jèhófà* wí. ‘Màá fi àwọn òfin mi sínú èrò wọn, inú ọkàn wọn sì ni màá kọ ọ́ sí.+ Màá di Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì di èèyàn mi.+
11 “‘Kálukú wọn kò tún ní máa kọ́ ọmọ ìbílẹ̀ rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ mọ́ pé: “Ẹ mọ Jèhófà!”* Nítorí gbogbo wọn á mọ̀ mí, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. 12 Torí màá ṣàánú wọn lórí ọ̀rọ̀ ìwà àìṣòdodo wọn, mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.’”+
-