-
Jeremáyà 50:20Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
20 “Ní ọjọ́ yẹn àti ní àkókò yẹn,” ni Jèhófà wí,
“A ó wá ẹ̀bi Ísírẹ́lì kiri,
Ṣùgbọ́n a kò ní rí ìkankan,
A kò sì ní rí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ Júdà,
Nítorí màá dárí ji àwọn tí mo jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù.”+
-
-
Hébérù 8:10-12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 “‘Nítorí májẹ̀mú tí màá bá ilé Ísírẹ́lì dá lẹ́yìn ìgbà yẹn nìyí,’ ni Jèhófà* wí. ‘Màá fi àwọn òfin mi sínú èrò wọn, inú ọkàn wọn sì ni màá kọ ọ́ sí.+ Màá di Ọlọ́run wọn, wọ́n á sì di èèyàn mi.+
11 “‘Kálukú wọn kò tún ní máa kọ́ ọmọ ìbílẹ̀ rẹ̀ àti arákùnrin rẹ̀ mọ́ pé: “Ẹ mọ Jèhófà!”* Nítorí gbogbo wọn á mọ̀ mí, látorí ẹni tó kéré jù lọ dórí ẹni tó tóbi jù lọ láàárín wọn. 12 Torí màá ṣàánú wọn lórí ọ̀rọ̀ ìwà àìṣòdodo wọn, mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.’”+
-
-
Hébérù 10:17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
17 Ó wá sọ pé: “Mi ò sì ní rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́ àti àwọn ìwà wọn tí kò bófin mu.”+
-