-
Ìdárò 2:11, 12Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
11 Ojú mi ti di bàìbàì nítorí omijé.+
Inú* mi ń dà rú.
A ti tú ẹ̀dọ̀ mi jáde sí ilẹ̀, nítorí ìṣubú ọmọbìnrin* àwọn èèyàn mi,+
Nítorí àwọn ọmọdé àti ọmọ jòjòló ń dá kú ní àwọn ojúde ìlú.+
ל [Lámédì]
12 Wọ́n ń béèrè lọ́wọ́ àwọn ìyá wọn pé: “Ọkà àti wáìnì dà?”+
Bí wọ́n ti ń kú lọ bí ẹni tó fara gbọgbẹ́ ní àwọn gbàgede ìlú,
Tí ẹ̀mí* wọn sì ń kú lọ lọ́wọ́ ìyá wọn.
-