17 ‘Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun sọ nìyí: “Wò ó, màá rán idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn*+ sí wọn, màá sì ṣe wọ́n bí ọ̀pọ̀tọ́ jíjẹrà* tó ti bà jẹ́ débi pé kò ṣeé jẹ.”’+
2 “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ẹni tó bá dúró sí ìlú yìí ni idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn* yóò pa.+ Àmọ́, ẹni tó bá fi ara rẹ̀ lé* ọwọ́ àwọn ará Kálídíà á máa wà láàyè, á jèrè ẹ̀mí rẹ̀, á sì wà láàyè.’*+