-
2 Àwọn Ọba 24:1, 2Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Nígbà ayé Jèhóákímù, Nebukadinésárì+ ọba Bábílónì wá gbéjà kò ó, Jèhóákímù sì fi ọdún mẹ́ta ṣe ìránṣẹ́ fún un. Àmọ́, ó yí pa dà, ó sì ṣọ̀tẹ̀. 2 Lẹ́yìn náà, Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í rán àwọn akónilẹ́rù* àwọn ará Kálídíà,+ ti àwọn ará Síríà, ti àwọn ọmọ Móábù àti ti àwọn ọmọ Ámónì sí i. Ó ń rán wọn sí Júdà léraléra láti pa á run, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Jèhófà+ gbẹnu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, wòlíì sọ.
-