ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • Jeremáyà 23:32
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 32 “Wò ó, mo dojú ìjà kọ àwọn wòlíì tó ń lá àlá èké,” ni Jèhófà wí, “àwọn tó ń rọ́ àlá, tí wọ́n sì ń kó àwọn èèyàn mi ṣìnà nítorí irọ́ wọn àti bí wọ́n ṣe ń fọ́nnu.”+

      “Ṣùgbọ́n mi ò rán wọn, bẹ́ẹ̀ ni mi ò pàṣẹ fún wọn. Nítorí náà, wọn ò ní ṣe àwọn èèyàn yìí láǹfààní kankan,”+ ni Jèhófà wí.

  • Jeremáyà 27:9
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    • 9 “‘“‘Torí náà, ẹ má fetí sí àwọn wòlíì yín, àwọn woṣẹ́woṣẹ́ yín, àwọn alálàá yín, àwọn onídán yín àti àwọn oníṣẹ́ oṣó yín, tí wọ́n ń sọ fún yín pé: “Ẹ kò ní sin ọba Bábílónì.”

  • Míkà 3:5
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  5 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí nípa àwọn wòlíì tó ń ṣi àwọn èèyàn mi lọ́nà,+

      Tí wọ́n ń kéde ‘Àlàáfíà!’+ nígbà tí wọ́n bá ń rí nǹkan jẹ,*+

      Àmọ́ tí wọ́n ń gbógun ti* ẹni tí kò fún wọn ní nǹkan kan jẹ:

  • Sefanáyà 3:4
    Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
    •  4 Aláfojúdi ni àwọn wòlíì rẹ̀, oníbékebèke ni wọ́n.+

      Àwọn àlùfáà rẹ̀ ń sọ ohun mímọ́ di ẹlẹ́gbin;+

      Wọ́n ń rú òfin.+

Yorùbá Publications (1987-2025)
Jáde
Wọlé
  • Yorùbá
  • Fi Ráńṣẹ́
  • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
  • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
  • Àdéhùn Nípa Lílò
  • Òfin
  • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
  • JW.ORG
  • Wọlé
Fi Ráńṣẹ́