5 mo wòkè, mo sì rí ọkùnrin kan tó wọ aṣọ ọ̀gbọ̀,+ ó sì de àmùrè wúrà tó wá láti Úfásì mọ́ ìbàdí rẹ̀. 6 Ara rẹ̀ dà bíi kírísóláítì,+ ojú rẹ̀ rí bíi mànàmáná, ẹyinjú rẹ̀ dà bí ògùṣọ̀ oníná, apá rẹ̀ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ dà bíi bàbà tó ń dán,+ ìró ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì dà bí ìró èrò púpọ̀.