13 Ó dájú pé wàá dìde, wàá sì ṣàánú Síónì,+
Torí àkókò ti tó láti ṣe ojú rere sí i;+
Àkókò tí a dá ti pé.+
14 Nítorí àwọn ìránṣẹ́ rẹ fẹ́ràn àwọn òkúta rẹ̀,+
Kódà, wọ́n nífẹ̀ẹ́ erùpẹ̀ rẹ̀.+
15 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò máa bẹ̀rù orúkọ Jèhófà,
Gbogbo ọba ayé yóò sì máa bẹ̀rù ògo rẹ.+