26 Wọn yóò máa gbé ibẹ̀, ààbò yóò sì wà lórí wọn,+ wọ́n á kọ́ ilé, wọ́n á gbin ọgbà àjàrà,+ nígbà tí mo bá ṣèdájọ́ gbogbo àwọn tó yí wọn ká tó ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà,+ ààbò yóò wà lórí wọn; wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run wọn.”’”
14 ‘Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, ẹ ó sì di alààyè,+ èmi yóò mú kí ẹ máa gbé lórí ilẹ̀ yín; ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, mo sì ti ṣe é,’ ni Jèhófà wí.”