8 “‘“Wàá gbàfiyèsí lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọjọ́. Ní àwọn ọdún tó kẹ́yìn, ìwọ yóò gbógun ja àwọn èèyàn tó ti bọ́ lọ́wọ́ idà, àwọn tó kóra jọ láti inú ọ̀pọ̀ èèyàn sórí àwọn òkè Ísírẹ́lì, tó ti di ahoro tipẹ́. Àárín àwọn èèyàn ni àwọn tó ń gbé ilẹ̀ yìí ti jáde, ààbò sì wà lórí gbogbo wọn.+