23 Àwọn ọmọ Ámónì àti àwọn ọmọ Móábù dojú kọ àwọn tó ń gbé agbègbè olókè Séírì+ láti pa wọ́n run pátápátá; nígbà tí wọ́n yanjú àwọn tó ń gbé Séírì tán, wọ́n dojú ìjà kọ ara wọn, wọ́n sì pa ara wọn.+
22 Èmi yóò bi ìtẹ́ àwọn ìjọba ṣubú, èmi yóò sì gba agbára lọ́wọ́ ìjọba àwọn orílẹ̀-èdè;+ èmi yóò bi kẹ̀kẹ́ ẹṣin àti àwọn tó gùn ún ṣubú, àwọn ẹṣin àti àwọn tó gùn wọ́n yóò sì ṣubú, kálukú wọn yóò sì fi idà pa arákùnrin rẹ̀.’”+