6 Jèhófà ní idà kan; ẹ̀jẹ̀ máa bò ó.
Ọ̀rá+ máa bò ó,
Ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ àgbò àti ewúrẹ́ máa bò ó,
Ọ̀rá kíndìnrín àwọn àgbò máa bò ó.
Torí pé Jèhófà ní ẹbọ ní Bósírà,
Ó máa pa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ní ilẹ̀ Édómù.+
7 Àwọn akọ màlúù igbó máa bá wọn sọ̀ kalẹ̀,
Àwọn akọ ọmọ màlúù pẹ̀lú àwọn alágbára.
Ẹ̀jẹ̀ máa rin ilẹ̀ wọn gbingbin,
Ọ̀rá sì máa rin iyẹ̀pẹ̀ wọn gbingbin.”
8 Torí Jèhófà ní ọjọ́ ẹ̀san,+
Ọdún ẹ̀san torí ẹjọ́ lórí Síónì.+