-
1 Kíróníkà 9:26, 27Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
26 Àwọn olórí* aṣọ́bodè mẹ́rin ló wà ní ipò ẹni tó ṣeé fọkàn tán. Ọmọ Léfì ni wọ́n, àwọn ló sì ń bójú tó àwọn yàrá* àti àwọn ibi ìṣúra tó wà nínú ilé Ọlọ́run tòótọ́.+ 27 Wọ́n máa ń wà níbi tí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ káàkiri ilé Ọlọ́run tòótọ́ láti òru mọ́jú, nítorí àwọn ló ń ṣe iṣẹ́ olùṣọ́, ọwọ́ wọn ni kọ́kọ́rọ́ máa ń wà, àwọn ló sì ń ṣí ilé náà láràárọ̀.
-