9 Tí àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá sì wá síwájú Jèhófà nígbà àjọ̀dún,+ kí àwọn tó bá gba ẹnubodè àríwá+ wọlé láti jọ́sìn gba ẹnubodè gúúsù+ jáde, kí àwọn tó bá sì gba ẹnubodè gúúsù wọlé gba ẹnubodè àríwá jáde. Ẹnikẹ́ni kò gbọ́dọ̀ gba ẹnubodè tó gbà wọlé jáde, ẹnubodè tó kọjú sí wọn ni kí wọ́n gbà jáde.