-
Ìsíkíẹ́lì 45:24Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
24 Yóò tún pèsè òṣùwọ̀n eéfà kan fún akọ ọmọ màlúù kọ̀ọ̀kan àti òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò kọ̀ọ̀kan, yóò sì tún pèsè òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì* kan fún òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 46:6, 7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
6 Ní ọjọ́ òṣùpá tuntun, ọrẹ náà yóò jẹ́ akọ ọmọ màlúù kan nínú agbo ẹran, akọ ọ̀dọ́ àgùntàn mẹ́fà àti àgbò kan; kí ara gbogbo wọn dá ṣáṣá.+ 7 Kí ọrẹ ọkà tó máa mú wá jẹ́ òṣùwọ̀n eéfà kan fún akọ ọmọ màlúù kan, òṣùwọ̀n eéfà kan fún àgbò àti ohunkóhun tí agbára rẹ̀ bá ká fún àwọn akọ ọ̀dọ́ àgùntàn. Kó sì mú òróró tó kún òṣùwọ̀n hínì kan wá fún òṣùwọ̀n eéfà kọ̀ọ̀kan.
-