11 “‘Torí náà, bí mo ti wà láàyè,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘torí pé ẹ fi àwọn òrìṣà ẹ̀gbin yín àti àwọn ohun ìríra tí ẹ̀ ń ṣe sọ ibi mímọ́ mi di aláìmọ́,+ èmi náà yóò kọ̀ yín;* mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín.+
4 Mi ò ní ṣàánú yín, mi ò sì ní yọ́nú sí yín,+ torí màá fi ìwà yín san yín lẹ́san. Ẹ ó jìyà gbogbo ohun ìríra tí ẹ ṣe.+ Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’+