-
Ìsíkíẹ́lì 10:15-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Àwọn kérúbù náà á sì dìde, àwọn ni ẹ̀dá alààyè* tí mo rí ní odò Kébárì,+ 16 tí àwọn kérúbù náà bá sì gbéra, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà á gbéra pẹ̀lú wọn; tí wọ́n bá sì na ìyẹ́ apá wọn kí wọ́n lè lọ sókè, àwọn àgbá kẹ̀kẹ́ náà kì í yí tàbí kí wọ́n kúrò lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn.+ 17 Tí wọ́n bá dúró, àwọn àgbá náà á dúró; tí wọ́n bá sì gbéra, àwọn àgbá náà á gbéra pẹ̀lú wọn, torí ẹ̀mí tó ń darí àwọn ẹ̀dá alààyè náà* wà nínú àwọn àgbá náà.
-