-
Jeremáyà 32:3, 4Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
3 Nítorí Sedekáyà ọba Júdà ti fi í sí àhámọ́,+ ọba sì sọ pé, “Kí nìdí tí o fi sọ tẹ́lẹ̀ báyìí? O sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Màá fi ìlú yìí lé ọwọ́ ọba Bábílónì, á sì gbà á,+ 4 Sedekáyà ọba Júdà kò ní lè sá mọ́ àwọn ará Kálídíà lọ́wọ́, nítorí ó dájú pé a ó fi í lé ọba Bábílónì lọ́wọ́, wọ́n á jọ rí ara wọn, wọ́n á sì sọ̀rọ̀ lójúkojú.”’+
-