4 Jónà bá wọnú ìlú náà, ó rin ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde pé: “Ogójì (40) ọjọ́ péré ló kù kí Nínéfè pa run.”
5 Àwọn ará ìlú Nínéfè wá gba Ọlọ́run gbọ́,+ wọ́n kéde pé kí gbogbo ìlú gbààwẹ̀, wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, látorí ẹni tó tóbi jù dórí ẹni tó kéré jù.