-
Ìsíkíẹ́lì 7:15-17Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
15 Idà wà níta,+ àjàkálẹ̀ àrùn àti ìyàn sì wà nínú. Idà ni yóò pa ẹnikẹ́ni tó bá wà ní pápá, ìyàn àti àjàkálẹ̀ àrùn sì máa run àwọn tó bá wà nínú ìlú.+ 16 Àwọn tó bá jàjà bọ́ yóò sá lọ sórí àwọn òkè, kálukú wọn á sì ké tẹ̀dùntẹ̀dùn torí àṣìṣe rẹ̀ bí àwọn àdàbà inú àfonífojì.+ 17 Gbogbo ọwọ́ wọn á rọ jọwọrọ, omi á sì máa ro tótó ní orúnkún wọn.*+
-