-
2 Àwọn Ọba 25:5-7Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
5 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé ọba, wọ́n sì bá a ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. 6 Lẹ́yìn náà, wọ́n gbá ọba mú,+ wọ́n mú un wá sọ́dọ̀ ọba Bábílónì ní Ríbúlà, wọ́n sì dá a lẹ́jọ́. 7 Wọ́n pa àwọn ọmọ Sedekáyà níṣojú rẹ̀; Nebukadinésárì wá fọ́ ojú Sedekáyà, ó fi ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ bàbà dè é, ó sì mú un wá sí Bábílónì.+
-
-
Jeremáyà 52:8Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
8 Àmọ́ àwọn ọmọ ogun Kálídíà lé ọba, wọ́n sì bá Sedekáyà+ ní aṣálẹ̀ tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jẹ́ríkò, gbogbo ọmọ ogun rẹ̀ sì tú ká kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.
-
-
Ìsíkíẹ́lì 12:12, 13Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
12 Ìjòyè àárín wọn yóò gbé ẹrù rẹ̀ lé èjìká, yóò sì lọ nínú òkùnkùn. Ó máa dá ògiri lu, yóò sì gbé ẹrù rẹ̀ gba inú ihò náà.+ Ó máa bo ojú rẹ̀ kó má bàa rí ilẹ̀.’ 13 Èmi yóò ju àwọ̀n mi sí i láti fi mú un.+ Màá wá mú un lọ sí Bábílónì, sí ilẹ̀ àwọn ará Kálídíà, àmọ́ kò ní rí i; ibẹ̀ ló sì máa kú sí.+
-