-
Ìsíkíẹ́lì 27:10, 11Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
-
-
10 Àwọn ará Páṣíà, Lúdì àti Pútì+ wà lára àwọn jagunjagun rẹ, àwọn ọkùnrin ogun rẹ.
Inú rẹ ni wọ́n gbé apata àti akoto* wọn kọ́ sí, wọ́n sì ṣe ọ́ lógo.
11 Àwọn ará Áfádì tó wà lára àwọn ọmọ ogun rẹ wà lórí ògiri rẹ yí ká,
Àwọn ọkùnrin onígboyà sì wà nínú àwọn ilé gogoro rẹ.
Wọ́n gbé àwọn apata* wọn kọ́ sára ògiri rẹ yí ká,
Wọ́n sì buyì kún ẹwà rẹ.
-