6 Ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
‘Àwọn tó ń ti Íjíbítì lẹ́yìn pẹ̀lú yóò ṣubú,
Agbára tó ń mú kó gbéra ga yóò sì wálẹ̀.’+
“‘Idà ni yóò pa wọ́n ní ilẹ̀ náà, láti Mígídólì+ dé Síénè,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 7 ‘Wọ́n á di ahoro ju àwọn ilẹ̀ yòókù lọ, àwọn ìlú rẹ̀ á sì di ahoro ju àwọn ìlú yòókù lọ.+