20 Àwọn ni ẹ̀dá alààyè* tí mo rí lábẹ́ ìtẹ́ Ọlọ́run Ísírẹ́lì ní odò Kébárì,+ mo wá mọ̀ pé kérúbù ni wọ́n. 21 Àwọn mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ní ojú mẹ́rin, ìyẹ́ apá mẹ́rin, ohun tó sì dà bí ọwọ́ èèyàn wà lábẹ́ ìyẹ́ apá wọn.+
8 Ní ti àwọn ẹ̀dá alààyè mẹ́rin náà, ọ̀kọ̀ọ̀kan ní ìyẹ́ mẹ́fà tí ojú kún ara rẹ̀ yí ká àti lábẹ́.+ Tọ̀sántòru ni wọ́n ń sọ pé: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà*+ Ọlọ́run, Olódùmarè, tó ti wà tipẹ́, tó wà báyìí, tó sì ń bọ̀.”+