2 Ọba wá pàṣẹ pé kí wọ́n pe àwọn àlùfáà onídán, àwọn pidánpidán, àwọn oṣó àti àwọn ará Kálídíà* láti rọ́ àwọn àlá ọba fún un. Torí náà, wọ́n wọlé, wọ́n sì dúró níwájú ọba.+
7 “Ìgbà yẹn ni àwọn àlùfáà onídán, àwọn pidánpidán, àwọn ará Kálídíà* àti àwọn awòràwọ̀+ wọlé wá. Nígbà tí mo rọ́ àlá náà fún wọn, wọn ò lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.+