32 Kí ni kí n tún sọ? Torí àkókò ò ní tó tí n bá ní kí n máa sọ̀rọ̀ nípa Gídíónì,+ Bárákì,+ Sámúsìn,+ Jẹ́fútà,+ Dáfídì,+ títí kan Sámúẹ́lì+ àti àwọn wòlíì yòókù. 33 Ìgbàgbọ́ mú kí wọ́n ṣẹ́gun àwọn ìjọba,+ wọ́n mú kí òdodo fìdí múlẹ̀, wọ́n rí àwọn ìlérí gbà,+ wọ́n dí ẹnu àwọn kìnnìún,+