29 Torí náà, mo pa á láṣẹ pé èèyàn èyíkéyìí, orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà tó bá sọ ohunkóhun tí kò dáa sí Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣe la máa gé e sí wẹ́wẹ́, a sì máa sọ ilé rẹ̀ di ilé ìyàgbẹ́ gbogbo èèyàn; torí kò sí ọlọ́run míì tó lè gbani là bí èyí.”+